28. Ki awọn enia ilẹ na ninu eyiti iwọ ti mú wa jade wá ki o má ba wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú wọn dé ilẹ na ti o ti ṣe ileri fun wọn, ati nitoriti o korira wọn, li o ṣe mú wọn jade wá lati pa wọn li aginjù.
29. Ṣugbọn sibẹ̀ enia rẹ ni nwọn iṣe, ati iní rẹ, ti iwọ mú jade nipa agbara nla rẹ, ati nipa ninà apa rẹ.