9. Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ.
10. Nigbati iwọ ba si jẹun tán ti o si yo, nigbana ni iwọ o fi ibukún fun OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori ilẹ rere na ti o fi fun ọ.
11. Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ṣe gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, li aipa ofin rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni:
12. Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀;
13. Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i;
14. Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú;
15. Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá;