Deu 34:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA.

6. O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni.

7. Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku.

8. Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari.

9. Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

10. Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju,

Deu 34