8. Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba;
9. Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́.
10. Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ.
11. OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́.
12. Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀.
13. Ati niti Josefu o wipe, Ibukún OLUWA ni ilẹ rẹ̀, fun ohun iyebiye ọrun, fun ìri, ati fun ibú ti o ba nisalẹ,
14. Ati fun eso iyebiye ti õrùn múwa, ati fun ohun iyebiye ti ndàgba li oṣoṣù,
15. Ati fun ohun pàtaki okenla igbãni, ati fun ohun iyebiye òke aiyeraiye,
16. Ati fun ohun iyebiye aiye ati ẹkún rẹ̀, ati fun ifẹ́ inurere ẹniti o gbé inu igbẹ́: jẹ ki ibukún ki o wá si ori Josefu, ati si atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀.