OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá.