1. NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei.
2. OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.
3. Bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun wa fi Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, lé wa lọwọ pẹlu: awa si kọlù u titi kò si kù ẹnikan silẹ fun u.
4. Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na; kò sí ilu kan ti awa kò gbà lọwọ wọn; ọgọta ilu, gbogbo ẹkùn Argobu, ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
5. Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi.