Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ.