Deu 28:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.

5. Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ.

6. Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade.

7. OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje.

8. OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

Deu 28