28. Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja;
29. Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.
30. Ṣugbọn Sihoni ọba Heṣboni kò jẹ ki a kọja lẹba on: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u li àiya le, o sọ ọkàn rẹ̀ di agídi, ki o le fi on lé ọ lọwọ, bi o ti ri li oni yi.
31. OLUWA si sọ fun mi pe, Wò o, emi ti bẹ̀rẹsi fi Sihoni ati ilẹ rẹ̀ fun ọ niwaju rẹ: bẹ̀rẹsi gbà a, ki iwọ ki o le ní ilẹ rẹ̀.
32. Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi.
33. OLUWA Ọlọrun si fi i lé wa lọwọ niwaju wa; awa si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀.
34. Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù: