Deu 2:23-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.)

24. Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun.

25. Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.

26. Mo si rán onṣẹ lati aginjù Kedemotu lọ sọdọ Sihoni ọba Heṣboni pẹlu ọ̀rọ alafia, wipe,

27. Jẹ ki emi ki o là ilẹ rẹ kọja lọ: ọ̀na opópo li emi o gbà, emi ki yio yà si ọtún tabi si òsi.

28. Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja;

Deu 2