Deu 18:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.

9. Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni.

10. Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́,

11. Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò.

12. Nitoripe gbogbo awọn ti nṣe nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi ni OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ.

13. Ki iwọ ki o pé lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ.

14. Nitori orilẹ-ède wọnyi ti iwọ o gbà, nwọn fetisi awọn alakiyesi-ìgba, ati si awọn alafọ̀ṣẹ: ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni, OLUWA Ọlọrun rẹ kò gbà fun ọ bẹ̃.

15. OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi;

16. Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.

17. OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ.

18. Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ.

Deu 18