Deu 17:17-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Bẹ̃ni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rẹ̀, ki àiya rẹ̀ ki o má ba yipada: bẹ̃ni ki o máṣe kó fadakà tabi wurá jọ fun ara rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ.

18. Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi:

19. Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn:

20. Ki àiya rẹ̀ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ́ rẹ̀ pẹ ni ijọba rẹ̀, on, ati awọn ọmọ rẹ̀, lãrin Israeli.

Deu 17