14. Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká;
15. Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ.
16. Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́.