Deu 16:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ki iwọ ki o si sun u, ki iwọ ki o si jẹ ẹ ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn: ki iwọ ki o si pada li owurọ̀, ki o si lọ sinu agọ́ rẹ.

8. Ijọ́ mẹfa ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu: ati ni ijọ́ keje ki ajọ kan ki o wà fun OLUWA Ọlọrun rẹ; ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹ́ kan.

9. Ọsẹ meje ni ki iwọ ki o kà fun ara rẹ: bẹ̀rẹsi ati kà ọ̀sẹ meje na lati ìgba ti iwọ ba tẹ̀ doje bọ̀ ọkà.

10. Ki iwọ ki o si pa ajọ ọ̀sẹ mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu ọrẹ ifẹ́-atinuwa ọwọ́ rẹ, ti iwọ o fi fun u, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti busi i fun ọ:

11. Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si.

12. Ki iwọ ki o si ma ranti pe, ẹrú ni iwọ ti jẹ́ ni Egipti: ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ṣe ìlana wọnyi.

13. Ki iwọ ki o si ma pa ajọ agọ́ mọ́ li ọjọ́ meje, lẹhin ìgba ti iwọ ba ṣe ipalẹmọ ilẹ-ipakà rẹ ati ibi-ifunti rẹ.

14. Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ.

Deu 16