9. Mo si sọ fun nyin ni ìgba na pe, Emi nikan kò le rù ẹrù nyin:
10. OLUWA Ọlọrun nyin ti mu nyin bisi i, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun fun ọ̀pọ.
11. Ki OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin ki o fi kún iye nyin ni ìgba ẹgbẹrun, ki o si busi i fun nyin, bi o ti ṣe ileri fun nyin!
12. Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin?
13. Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọ́n wá, ati amoye, ati ẹniti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀ya nyin, emi o si fi wọn jẹ olori nyin.
14. Ẹnyin si da mi li ohùn, ẹ si wipe, Ohun ti iwọ sọ nì, o dara lati ṣe.
15. Bẹ̃ni mo mú olori awọn ẹ̀ya nyin, awọn ọlọgbọ́n ọkunrin, ẹniti a mọ̀, mo si fi wọn jẹ olori nyin, olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwa-mẹwa, ati awọn olori gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya nyin.
16. Mo si fi aṣẹ lelẹ fun awọn onidajọ nyin nigbana pe, Ẹ ma gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ma ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀.
17. Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju ni idajọ; ẹ gbọ́ ti ewe gẹgẹ bi ti àgba; ẹ kò gbọdọ bẹ̀ru oju enia; nitoripe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ran ti o ba si ṣoro fun nyin, ẹ mú u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́ ọ.
18. Emi si fi aṣẹ ohun gbogbo ti ẹnyin o ma ṣe lelẹ fun nyin ni ìgba na.
19. Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea.