19. Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.
20. Igi ti iwọ ri ti o si dagba, ti o si lagbara, eyi ti giga rẹ̀ kan ọrun, ti a si ri i de gbogbo aiye;
21. Eyi ti ewe rẹ̀ lẹwà, ti eso rẹ̀ si pọ̀, ninu eyi ti onjẹ si wà fun gbogbo ẹda, labẹ eyi ti awọn ẹranko igbẹ ngbe, lori ẹka eyi ti awọn ẹiyẹ oju-ọrun ni ibugbe wọn.
22. Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.
23. Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,
24. Ọba, itumọ rẹ̀ li eyi, ati eyiyi li aṣẹ Ọga-ogo, ti o wá sori ọba, oluwa mi: