40. Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna.
41. Ati gẹgẹ bi iwọ ti ri ẹsẹ ati ọmọkasẹ ti o jẹ apakan amọ̀ amọkoko, ati apakan irin, ni ijọba na yio yà si ara rẹ̀; ṣugbọn ipá ti irin yio wà ninu rẹ̀, niwọn bi iwọ ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀.
42. Gẹgẹ bi ọmọkasẹ na ti jẹ apakan irin ati apakan amọ̀, bẹ̃li apakan ijọba na yio lagbara, apakan yio si jẹ ohun fifọ.
43. Ati gẹgẹ bi iwọ si ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀, nwọn o da ara wọn pọ mọ iru-ọmọ enia, ṣugbọn nwọn kì yio fi ara wọn mọ ara wọn, gẹgẹ bi irin kì ti idapọ mọ amọ̀.