34. Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu.
35. Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye.
36. Eyiyi li alá na; awa o si sọ itumọ rẹ̀ pẹlu niwaju ọba.
37. Iwọ ọba, li ọba awọn ọba: nitori Ọlọrun ọrun ti fi ijọba, agbara, ati ipá, ati ogo fun ọ.
38. Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi.
39. Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye.
40. Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna.