Dan 10:17-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitoripé bawo ni ọmọ-ọdọ oluwa mi yi yio ti ṣe le ba oluwa mi yi sọ̀rọ? ṣugbọn bi o ṣe temi ni, lojukanna, agbara kò kù ninu mi, bẹ̃ni kò si kù ẽmi ninu mi.

18. Nigbana ni ẹnikan ti o ni aworan enia wá o si tun fi ọwọ tọ́ mi, o si mu mi lara le,

19. O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le.

20. Nigbana ni o wipe, Iwọ, ha mọ̀ idi ohun ti mo tọ̀ ọ wá si? nisisiyi li emi o si yipada lọ iba balogun Persia jà: nigbati emi ba si jade lọ, kiyesi i, balogun Hellene yio wá.

21. Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.

Dan 10