Amo 6:3-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ẹnyin ti o sún ọjọ ibi siwaju, ti ẹ si mu ibùgbe ìwa-ipá sunmọ tòsi;

4. Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo;

5. Ti nwáhùn si iró orin fioli, ti nwọn si nṣe ohun-ikọrin fun ara wọn, bi Dafidi;

6. Awọn ti nmuti ninu ọpọ́n waini, ti nwọn si nfi olori ororo kun ara wọn; ṣugbọn nwọn kò banujẹ nitori ipọnju Josefu.

Amo 6