23. Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ.
24. Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla.
25. Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli.
26. Ṣugbọn ẹnyin ti rù agọ Moloku ati Kiuni nyin, awọn ere nyin, irawọ̀ òriṣa nyin, ti ẹ ṣe fun ara nyin.
27. Nitorina, emi o mu ki ẹ lọ si igbèkun rekọja Damasku, li Oluwa wi, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.