Amo 5:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.

12. Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn.

13. Nitorina ẹni-oye yio dakẹ nigbana; nitori akòko ibi ni.

14. Ẹ ma wá ire, kì isi iṣe ibi, ki ẹ ba le yè; bẹ̃ni Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, yio si pẹlu nyin, bi ẹnyin ti wi.

15. Ẹ korira ibi, ẹ si fẹ́ ire, ki ẹ si fi idajọ gunlẹ ni bodè; boya Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun yio ṣe ojurere si iyokù Josefu.

16. Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.

17. Ati ni gbogbo ọ̀gba àjara ni isọkún yio gbe wà: nitori emi o kọja lãrin rẹ, li Oluwa wi.

Amo 5