11. Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.
12. Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli.
13. Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.