1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi, ẹnyin ọmọ malu Baṣan, ti o wà li oke nla Samaria, ti o nni talakà lara, ti o ntẹ̀ alaini rẹ́, ti o nwi fun oluwa wọn pe, Gbe wá, ki a si mu.
2. Oluwa Ọlọrun ti bura ninu iwà-mimọ́ rẹ̀, pe, Sa wò o, ọjọ wọnni yio de ba nyin, ti on o fi ìwọ gbe nyin kuro, yio si fi ìwọ-ẹja gbe iran nyin.
3. Ati ni ibi yiya odi wọnni li ẹnyin o ba jade lọ, olukuluku niwaju rẹ̀ gan; ẹnyin o si gbe ara nyin sọ si Harmona, li Oluwa wi.
4. Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta.