A. Oni 9:36-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Nigbati Gaali si ri awọn enia na, o wi fun Sebulu pe, Wò o, awọn enia nti ori òke sọkalẹ wa. Sebulu si wi fun u pe, Ojiji òke wọnni ni iwọ ri bi ẹnipe enia.

37. Gaali si tun wipe, Wò o, awọn enia nti òke sọkalẹ li agbedemeji ilẹ wá, ẹgbẹ kan si nti ọ̀na igi-oaku Meonenimu wá.

38. Nigbana ni Sebulu wi fun u pe, Nibo li ẹnu rẹ wà nisisiyi, ti iwọ fi wipe, Tani Abimeleki, ti awa o fi ma sìn i? awọn enia ti iwọ ti gàn kọ́ ni iwọnyi? jọwọ jade lọ, nisisiyi, ki o si bà wọn jà.

39. Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà.

40. Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode.

41. Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu.

42. O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki.

43. On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn.

44. Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn.

45. Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i.

A. Oni 9