3. Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì.
4. Gideoni si dé odò Jordani, o si rekọja, on ati ọdunrun ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀, o di ãrẹ, ṣugbọn nwọn nlepa sibẹ̀.
5. On si wi fun awọn ọkunrin Sukkotu pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ìṣu-àkara melokan fun awọn enia wọnyi ti ntọ̀ mi lẹhin: nitoriti o di ãrẹ fun wọn, emi si nlepa Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani.
6. Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ?
7. Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin.
8. On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn.
9. On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀.