1. AWỌN ọkunrin Efraimu si wi fun u pe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa bayi, ti iwọ kò fi pè wa, nigbati iwọ nlọ bá awọn ara Midiani jà? Nwọn si bá a sọ̀ gidigidi.
2. On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ?
3. Ọlọrun sá ti fi awọn ọmọ-alade Midiani lé nyin lọwọ, Orebu ati Seebu: kini mo si le ṣe bi nyin? Nigbana ni inu wọn tutù si i, nigbati o ti wi eyinì.