4. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ.
5. Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi.
6. Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi.
7. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀.
8. Awọn enia na si mu onjẹ ati ipè li ọwọ́ wọn: on si rán gbogbo Israeli lọ, olukuluku sinu agọ́ rẹ̀, o si da ọdunrun ọkunrin nì duro: ibudó Midiani si wà nisalẹ rẹ̀ li afonifoji.