A. Oni 6:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́.

11. Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani.

12. Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara.

13. Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ.

14. OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi?

15. O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi.

16. OLUWA si wi fun u pe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ, iwọ o si kọlù awọn Midiani bi ọkunrin kan.

17. On si wi fun u pe, Bi o ba ṣepe mo ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, njẹ fi àmi kan hàn mi pe iwọ bá mi sọ̀rọ.

A. Oni 6