A. Oni 21:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nwọn si wipe, Ilẹ-iní kan yio wà fun awọn ti o ti sálà ni Benjamini, ki ẹ̀ya kan ki o má ba parun kuro ni Israeli.

18. Ṣugbọn awa kò lè fi aya fun wọn ninu awọn ọmọbinrin wa: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti bura, wipe, Egún ni fun ẹniti o ba fi aya fun Benjamini.

19. Nwọn si wipe, Kiyesi i, ajọ OLUWA wà li ọdọdún ni Ṣilo ni ìha ariwa Beti-eli, ni ìha ìla-õrùn ti opópo ti o lọ soke lati Beti-eli lọ titi dé Ṣekemu, ati ni ìha gusù ti Lebona.

20. Nwọn si fi aṣẹ fun awọn ọmọ Benjamini wipe, Ẹ lọ ki ẹ si ba sinu ọgbà-àjara;

21. Ki ẹ si wò, si kiyesi i, bi awọn ọmọbinrin Ṣilo ba jade wá lati jó ninu ijó wọnni, nigbana ni ki ẹnyin ki o jade lati inu ọgbà-àjara wá, ki olukuluku ọkunrin nyin ki o si mú aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Ṣilo, ki ẹnyin ki o si lọ si ilẹ Benjamini.

22. Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi.

23. Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn.

A. Oni 21