A. Oni 2:19-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. O si ṣe, nigbati onidajọ na ba kú, nwọn a si pada, nwọn a si bà ara wọn jẹ́ jù awọn baba wọn lọ, ni titọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma fi ori balẹ fun wọn; nwọn kò dẹkun iṣe wọn, ati ìwa-agidi wọn.

20. Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi;

21. Emi pẹlu ki yio lé ọkan jade mọ́ kuro niwaju wọn ninu awọn orilẹ-ède, ti Joṣua fisilẹ nigbati o kú:

22. Ki emi ki o le ma fi wọn dan Israeli wò, bi nwọn o ma ṣe akiyesi ọ̀na OLUWA lati ma rìn ninu rẹ̀, bi awọn baba wọn ti ṣe akiyesi rẹ̀, tabi bi nwọn ki yio ṣe e.

23. OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ.

A. Oni 2