7. Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe.
8. Nwọn si wá sọdọ awọn arakunrin wọn si Sora ati Eṣtaolu: awọn arakunrin wọn si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin wi?
9. Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na.
10. Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ.
11. Awọn enia idile Dani si ti ibẹ̀ lọ, lati Sora ati lati Eṣtaolu, ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun;