A. Oni 18:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ.

11. Awọn enia idile Dani si ti ibẹ̀ lọ, lati Sora ati lati Eṣtaolu, ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun;

12. Nwọn si gòke lọ, nwọn si dó si Kiriati-jearimu, ni Juda: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ̀ na ni Mahane-dani titi o fi di oni yi: kiyesi i, o wà lẹhin Kiriati-jearimu.

13. Nwọn si kọja lati ibẹ̀ lọ si ilẹ òke Efraimu, nwọn si wá si ile Mika.

14. Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe.

15. Nwọn si yà sibẹ̀, nwọn si wá si ile ọmọkunrin Lefi na, ani si ile Mika, nwọn si bère alafia rẹ̀.

16. Awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun ninu awọn ọmọ Dani, duro li ẹnu-ọ̀na.

A. Oni 18