A. Oni 17:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.

7. Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀.

8. Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ.

9. Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri.

10. Mika si wi fun u pe, Bá mi joko, ki iwọ ki o ma ṣe baba ati alufa fun mi, emi o ma fi owo fadakà mẹwa fun ọ li ọdún, adápe aṣọ kan, ati onjẹ rẹ. Bẹ̃ni ọmọ Lefi na si wọle.

A. Oni 17