9. Obinrin na si ní awọn kan, ti nwọn lumọ́ ninu yará. On si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. On si já okùn na, gẹgẹ bi owú ti ijá nigbati o ba kan iná. Bẹ̃li a kò mọ̀ agbara rẹ̀.
10. Delila si wi fun Samsoni pe, Kiyesi i, iwọ tàn mi jẹ, o si purọ́ fun mi: wi fun mi, emi bẹ̀ ọ, kili a le fi dè ọ.
11. On si wi fun u pe, Bi nwọn ba le fi okùn titun ti a kò ti lò rí dè mi le koko, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
12. Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu.
13. Delila si wi fun Samsoni pe, Titi di isisiyi iwọ ntàn mi ni, iwọ si npurọ́ fun mi: sọ fun mi, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi iwọ ba wun ìdi irun meje ti o wà li ori mi.
14. On si fi ẽkàn dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju orun rẹ̀, o si fà ẽkàn ìti na pẹlu ihunṣọ rẹ̀ lọ.
15. On si wi fun u pe, Iwọ ha ti ṣe wipe, Emi fẹ́ ọ, nigbati ọkàn rẹ kò ṣedede pẹlu mi? iwọ ti tàn mi ni ìgba mẹta yi, iwọ kò si sọ ibiti agbara nla rẹ gbé wà fun mi.
16. O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú.
17. Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
18. Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn.
19. O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.