8. On si kọlù wọn, o si pa wọn ni ipakupa: o si sọkalẹ o si joko ni pàlàpálá apata Etamu.
9. Nigbana li awọn Filistini gòke lọ, nwọn si dótì Juda, nwọn si tẹ́ ara wọn lọ bẹrẹ ni Lehi.
10. Awọn ọkunrin Juda si wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe gòke tọ̀ wa wá? Nwọn si dahùn wipe, Lati dè Samsoni li awa ṣe wá, lati ṣe si i gẹgẹ bi on ti ṣe si wa.
11. Nigbana li ẹgbẹdogun ọkunrin Juda sọkalẹ lọ si palapala apata Etamu, nwọn si wi fun Samsoni, pe, Iwọ kò mọ̀ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? On si wi fun wọn pe, Gẹgẹ bi nwọn ti ṣe si mi, bẹ̃li emi ṣe si wọn.
12. Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi.
13. Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.