16. Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi?
17. O si sọkun niwaju rẹ̀ titi ijọ́ meje ti àse na gbà: O si ṣe ni ijọ́ keje, o si já a fun u, nitoripe on ṣe e li aisimi pupọ̀, on si já alọ́ na fun awọn ọmọ enia rẹ̀.
18. Awọn ọkunrin ilunla na si wi fun u ni ijọ́ keje ki õrùn ki o to wọ̀ pe, Kili o dùn jù oyin lọ? kili o si lí agbara jù kiniun lọ? On si wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin kò fi ẹgbọrọ abo-malu mi tulẹ, ẹnyin kì ba ti mọ̀ alọ́ mi.
19. Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀.
20. Nwọn si fi obinrin Samsoni fun ọkan ninu awọn ẹgbẹ rẹ̀, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀.