A. Oni 14:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAMSONI si sọkalẹ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini.

2. O si gòke wá, o si sọ fun baba on iya rẹ̀, o si wipe, Emi ri obinrin kan ni Timna ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini: njẹ nitorina ẹ fẹ́ ẹ fun mi li aya.

3. Nigbana ni baba on iya rẹ̀ wi fun u pe, Kò sí obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakunrin rẹ, tabi ninu gbogbo awọn enia mi, ti iwọ fi nlọ ní obinrin ninu awọn alaikọlà Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ̀ pe, Fẹ́ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi.

A. Oni 14