A. Oni 11:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nwọn si wi fun Jefta pe, Wá, jẹ́ olori wa, ki awa ki o le bá awọn ọmọ Ammoni jà.

7. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Ẹnyin kò ha ti korira mi, ẹnyin kò ha ti lé mi kuro ni ile baba mi? ẽ si ti ṣe ti ẹnyin fi tọ̀ mi wá nisisiyi nigbati ẹnyin wà ninu ipọnju?

8. Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Nitorina li awa ṣe pada tọ̀ ọ nisisiyi, ki iwọ ki o le bá wa lọ, ki o si bá awọn ọmọ Ammoni jà, ki o si jẹ́ olori wa ati ti gbogbo awọn ara Gileadi.

9. Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Bi ẹnyin ba mú mi pada lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti OLUWA ba si fi wọn fun mi, emi o ha jẹ́ olori nyin bi?

10. Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Jẹ ki OLUWA ki o ṣe ẹlẹri lãrin wa, lõtọ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ bẹ̃li awa o ṣe.

11. Nigbana ni Jefta bá awọn àgba Gileadi lọ, awọn enia na si fi i jẹ́ olori ati balogun wọn: Jefta si sọ gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ niwaju OLUWA ni Mispa.

A. Oni 11