14. Jefta si tun rán onṣẹ si ọba awọn ọmọ Ammoni:
15. O si wi fun u pe, Bayi ni Jefta wi, Israeli kò gbà ilẹ Moabu, tabi ilẹ awọn ọmọ Ammoni:
16. Ṣugbọn nigbati Israeli gòke ti Egipti wá, ti nwọn si nrìn li aginjù, titi dé Okun Pupa, ti nwọn si dé Kadeṣi;
17. Nigbana ni Israeli rán onṣẹ si ọba Edomu, wipe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja ni ilẹ rẹ: ṣugbọn ọba Edomu kò gbọ́. Bẹ̃ gẹgẹ o si ranṣẹ si ọba Moabu pẹlu: ṣugbọn kò fẹ́: Israeli si joko ni Kadeṣi.
18. Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu.
19. Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn Amori, ọba Heṣboni; Israeli si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o kọja lãrin ilẹ rẹ si ipò mi.
20. Ṣugbọn Sihoni kò gbẹkẹle Israeli lati kọja li àgbegbe rẹ̀: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo enia rẹ̀ jọ, nwọn si dó ni Jahasi, nwọn si bá Israeli jagun.