14. Kí wọn má máa lo àkókò wọn lórí ìtàn àròsọ àwọn Juu ati ìlànà àwọn eniyan tí wọ́n ti yapa kúrò lọ́nà òtítọ́.
15. Gbogbo nǹkan ni ó mọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ṣugbọn kò sí nǹkankan tí ó mọ́ fún àwọn alaigbagbọ tí èrò wọn ti wọ́, nítorí èrò wọn ati ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọ́.
16. Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.