Tẹsalonika Kinni 4:16-18 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde.

17. A óo wá gbé àwa tí ó kù lẹ́yìn, tí a wà láàyè, lọ pẹlu wọn ninu awọsanma, láti lọ pàdé Oluwa ní òfuurufú, a óo sì máa wà lọ́dọ̀ Oluwa laelae.

18. Ẹ máa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu ara yín ninu.

Tẹsalonika Kinni 4