Samuẹli Kinni 6:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.

16. Àwọn ọba Filistini ń wò wọ́n bí wọ́n ti ń ṣe, lẹ́yìn náà, wọ́n yipada sí ìlú Ekironi ní ọjọ́ náà gan-an.

17. Àwọn ará Filistia fi kókó ọlọ́yún marun-un náà tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ìlú kọ̀ọ̀kan; Aṣidodu, Gasa, Aṣikeloni, Gati ati Ekironi.

Samuẹli Kinni 6