4. Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
5. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá.
6. OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún.
7. Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.”