Samuẹli Kinni 29:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ.

7. Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.”

8. Dafidi dáhùn pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ìdí rẹ̀ tí n kò fi ní lè lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jà, nígbà tí o kò rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ mi láti ìgbà tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?”

9. Akiṣi sì dáhùn pé, “Nítòótọ́ ni, mo mọ̀ pé o jẹ́ ẹni rere bí angẹli OLUWA, ṣugbọn àwọn olórí ogun ti sọ pé, o kò lè bá wa lọ sójú ogun.

10. Nítorí náà, dìde ní òwúrọ̀, ìwọ ati àwọn iranṣẹ oluwa rẹ, tí wọ́n bá ọ wá, kí ẹ sì máa lọ ní kété tí ilẹ̀ bá ti mọ́.”

11. Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá dìde, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Filistini, àwọn ọmọ ogun Filistini sì lọ sí Jesireeli.

Samuẹli Kinni 29