5. Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?”
6. Akiṣi fún un ní ìlú Sikilagi, nítorí náà ni Sikilagi fi jẹ́ ti àwọn ọba Juda títí di òní yìí.
7. Dafidi gbé ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún kan ati oṣù mẹrin.
8. Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti.
9. Dafidi pa gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin, ó sì kó àwọn aguntan, mààlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ràkúnmí wọn, ati aṣọ wọn, ó sì pada lọ bá Akiṣi.