27. Dafidi ati àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ pa igba (200) Filistini, ó sì kó awọ adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kí ó lè fẹ́ ọmọ ọba. Saulu sì fi ọmọbinrin rẹ̀, Mikali, fún Dafidi.
28. Saulu rí i dájúdájú pé OLUWA wà pẹlu Dafidi ati pé Mikali ọmọ òun fẹ́ràn Dafidi.
29. Nítorí náà, ó bẹ̀rù Dafidi sí i, ó sì ń bá Dafidi ṣe ọ̀tá títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
30. Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn.