9. Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.
10. Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’
11. OLUWA bá rán Jerubaali ati Baraki, ati Jẹfuta ati èmi, Samuẹli, láti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín káàkiri, ó sì jẹ́ kí ẹ wà ní alaafia.
12. Ṣugbọn nígbà tí ẹ rí i pé Nahaṣi, ọba Amoni fẹ́ gbé ogun tì yín, ẹ kọ OLUWA lọ́ba, ẹ wí fún mi pé, ẹ fẹ́ ọba tí yóo jẹ́ alákòóso yín.