9. Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé,
10. ẹni tí ó wá ròyìn ikú Saulu fún mi ní Sikilagi rò pé ìròyìn ayọ̀ ni òun mú wá fún mi, ṣugbọn mo ní kí wọn mú un kí wọ́n pa á. Ó jẹ èrè ìròyìn ayọ̀ rẹ̀, tí ó mú wá fún mi.
11. Báwo ni yóo ti burú tó fún àwọn ẹni ibi, tí wọ́n pa aláìṣẹ̀ sórí ibùsùn ninu ilé rẹ̀? Ṣé n kò ní gbẹ̀san pípa tí ẹ pa á lára yín, kí n sì pa yín rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé?”