Samuẹli Keji 22:48-51 BIBELI MIMỌ (BM)

48. Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi;

49. ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.“OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ,o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.

50. Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

51. Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn,àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!”

Samuẹli Keji 22